Bible Explorer

Ṣàwárí › Ọba àti Kronika lẹ́gbẹ̀ẹ́ ara wọn › Solomoni

Ọba àti Kronika lẹ́gbẹ̀ẹ́ ara wọn · Solomoni

Ikú Solomoni

1Ọb 11:41–43 · 2Kro 9:29–31

1 Ọba

1Ọb 11:41–43

41Ìyókù iṣẹ́ Solomoni àti gbogbo èyí tí ó ṣe, àti ọgbọ́n rẹ̀, a kò ha kọ wọ́n sínú ìwé ìṣe Solomoni bí?

42Solomoni sì jẹ ọba ní Jerusalẹmu lórí gbogbo Israẹli ní ogójì ọdún.

43Nígbà náà ni Solomoni sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín ní ìlú Dafidi baba rẹ̀. Rehoboamu ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

2 Kronika

2Kro 9:29–31

29Àti gẹ́gẹ́ bí ìyókù iṣẹ́ ìjọba Solomoni, láti ìbẹ̀rẹ̀ títí dé òpin, ṣé a kò kọ wọ́n sínú ìwé ìtàn Natani wòlíì, àti nínú ìsọtẹ́lẹ̀ Ahijah ará Ṣilo àti nínú ìran Iddo, wòlíì tí o so nípa Jeroboamu ọmọ Nebati?

30Solomoni jẹ ọba ní Jerusalẹmu lórí gbogbo àwọn Israẹli fún ogójì ọdún

31Solomoni sì sùn pẹ̀lú àwọn baba rẹ̀, a sì sin ín ní ìlú Dafidi baba rẹ̀, Rehoboamu, ọmọ rẹ̀ sì jẹ ọba ní ipò rẹ̀.

A sàmì sí: àwọn ọ̀rọ̀ tí gbogbo àkọsílẹ̀ ní, nínú ìtumọ̀ tí o ń kà. A kò sàmì sí àwọn ọ̀rọ̀ tí ó wọ́pọ̀ jùlọ (“àti”, “ó”); ọ̀rọ̀ tí ó wà ní ọ̀nà mìíràn lè máà ní àmì.

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní · A fi ọwọ́ yan àwọn abala tí ó jọra láti inú ọ̀rọ̀ Bíbélì, a sì ṣàyẹ̀wò wọn pẹ̀lú ìtọ́kasí OpenBible.info (CC BY). Ìṣẹ̀lẹ̀ kan náà tàbí ọ̀rọ̀ kan náà nìkan ni a fi sí ẹ̀gbẹ́ ara wọn. OpenBible.info · CC BY