Ojú-ìwé àkọ́kọ́ › Ohun tí Bíbélì sọ › Ọgbọ́n
Ìgbésí ayé àti iṣẹ́
Ohun tí Bíbélì sọ nípa Ọgbọ́n
Àwọn ẹsẹ tí àwọn òǹkàwé máa ń yíjú sí jùlọ fún àkòrí yìí (10), tí a fà yọ ní kíkún láti inú Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní.
Jk 1:5
Bí ó bá ku ọgbọ́n fún ẹnikẹ́ni, kí ó béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run ẹni tí fi fún gbogbo ènìyàn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀, tí kì í sì ka àlébù sí; a ó sì fi fún un.Òw 1:7
Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìbẹ̀rẹ̀ ìmọ̀, ṣùgbọ́n aláìgbọ́n kẹ́gàn ọgbọ́n àti ẹ̀kọ́.Jk 3:17
Ṣùgbọ́n ọgbọ́n tí ó ti òkè wá jẹ́ mímọ́ ní àkọ́kọ́, ti àlàáfíà, àti ti ìrẹ̀lẹ̀, kì í sì í ṣòro láti bẹ̀, ó kún fún àánú àti fún èso rere, kì í ṣe ojúsàájú, a sì máa sọ òtítọ́.Ef 5:15
Nítorí náà ẹ kíyèsi láti máa rìn ní ìwà pípé, kì í ṣé bí àwọn òmùgọ̀, ṣùgbọ́n bí àwọn ọlọ́gbọ́n;Òw 2:6
Nítorí Olúwa ni ó ń fún ni ní ọgbọ́n, láti ẹnu rẹ̀ sì ni ìmọ̀ àti òye ti ń wá.Mt 10:16
“Mò ń rán yín lọ gẹ́gẹ́ bí àgùntàn sáàrín ìkookò. Nítorí náà, kí ẹ ní ìṣọ́ra bí ejò, kí ẹ sì ṣe onírẹ̀lẹ̀ bí àdàbà.Jk 3:13–14
Ta ni ó gbọ́n tí ó sì ní ìmọ̀ nínú yín? Ẹ jẹ́ kí ó fi iṣẹ́ rẹ̀ hàn nípa ìwà rere, nípa ìwà tútù ti ọgbọ́n. Ṣùgbọ́n bí ẹ̀yin bá ní owú kíkorò àti ìjà ní ọkàn yín, ẹ má ṣe ṣe féfé, ẹ má sì ṣèké sí òtítọ́.Sm 111:10
Ìbẹ̀rù Olúwa ni ìpilẹ̀ṣẹ̀ ọgbọ́n: òye dáradára ni yóò máa ṣe òfin rẹ̀, ìyìn rẹ̀ dúró láé.Su 7:12
Ọgbọ́n jẹ́ ààbò gẹ́gẹ́ bí owó ti jẹ́ ààbò ṣùgbọ́n àǹfààní òye ni èyí pé ọgbọ́n a máa tọ́jú ẹ̀mí ẹni tí ó bá ní.Òw 19:20
Fetí sí ìmọ̀ràn kí o sì gba ẹ̀kọ́, ní ìgbẹ̀yìn gbẹ́yín ìwọ yóò di ọlọ́gbọ́n.Àwọn ẹsẹ tí àwọn òǹkàwé máa ń wá jù fún kókó yìí nìyí — kì í ṣe ẹ̀kọ́ nípa rẹ̀. Ka ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú orí rẹ̀.
Orísun
Àwọn ẹsẹ àkòrí kọ̀ọ̀kan àti ètò wọn: dátà àkòrí OpenBible.info, gẹ́gẹ́ bí ìbò àwọn òǹkàwé: OpenBible.info · CC BY 4.0
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní · © 2009, 2017 Biblica, Inc., CC BY-SA 4.0; changed: footnotes, headings and the letters over Psalm 119 left out, verses in the app's numbering. The original work by Biblica, Inc. is available for free at www.biblica.com and open.bible.