Ojú-ìwé àkọ́kọ́ › Ohun tí Bíbélì sọ › Ìyìn àti ìjọsìn
Ìgbàgbọ́
Ohun tí Bíbélì sọ nípa Ìyìn àti ìjọsìn
Àwọn ẹsẹ tí àwọn òǹkàwé máa ń yíjú sí jùlọ fún àkòrí yìí (10), tí a fà yọ ní kíkún láti inú Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní.
Isa 61:3
àti láti pèsè fún àwọn tí inú wọn bàjẹ́ ní Sioni láti dé wọn ládé ẹwà dípò eérú, òróró ayọ̀ dípò ọ̀fọ̀, àti aṣọ ìyìn dípò ìpòrúru ọkàn. A ó sì pè wọ́n ní igi óákù òdodo, irúgbìn Olúwa láti fi ọláńlá rẹ̀ hàn.Sm 150:6
Jẹ́ kí gbogbo ohun tí ó ní ẹ̀mí yin Olúwa. Ẹ fi ìyìn fún Olúwa.Hb 13:15
Ǹjẹ́ nípasẹ̀ rẹ̀, ẹ jẹ́ kí a máa rú ẹbọ ìyìn si Ọlọ́run nígbà gbogbo, èyí yìí ni èso ètè wa, tí ń jẹ́wọ́ orúkọ rẹ̀.Jh 4:24
Ẹ̀mí ni Ọlọ́run: àwọn ẹni tí ń sìn ín kò lè ṣe aláìsìn ín ní Ẹ̀mí àti ní òtítọ́.”Sm 150:2
Ẹ yìn ín fún iṣẹ́ agbára rẹ̀. Ẹ yìn ín fún títóbi rẹ̀ tí ó tayọ̀.Jh 4:23
Ṣùgbọ́n àkókò ń bọ̀, ó sì dé tán nísinsin yìí, nígbà tí àwọn olùsìn tòótọ́ yóò máa sin Baba ní ẹ̀mí àti ní òtítọ́, nítorí irú wọn ni Baba ń wá kí ó máa sin òun.Sm 106:1
Yin Olúwa! Ẹ fi ìyìn fún Olúwa, nítorí tí ó ṣeun. Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa nítorí tí ó ṣeun, nítorí tí ìfẹ́ rẹ̀ dúró láéláé.Sm 99:3
Kí wọ́n sì yin orúkọ rẹ̀ tí ó tóbi tí ó ni ẹ̀rù, Mímọ́ ni Òun.Sm 71:8
Ìyìn rẹ̀ kún ẹnu mi, ó ń sọ ti ọlá rẹ ní ọjọ́ gbogbo.Sm 109:30
Pẹ̀lú ẹnu mi èmi yóò máa yin Olúwa gidigidi ní àárín ọ̀pọ̀ ènìyàn èmi yóò máa yìn ín.Àwọn ẹsẹ tí àwọn òǹkàwé máa ń wá jù fún kókó yìí nìyí — kì í ṣe ẹ̀kọ́ nípa rẹ̀. Ka ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú orí rẹ̀.
Orísun
Àwọn ẹsẹ àkòrí kọ̀ọ̀kan àti ètò wọn: dátà àkòrí OpenBible.info, gẹ́gẹ́ bí ìbò àwọn òǹkàwé: OpenBible.info · CC BY 4.0
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní · © 2009, 2017 Biblica, Inc., CC BY-SA 4.0; changed: footnotes, headings and the letters over Psalm 119 left out, verses in the app's numbering. The original work by Biblica, Inc. is available for free at www.biblica.com and open.bible.