Bible Explorer Gba àpù

Ṣàwárí › Ìrìn-àjò › Àwọn ìrìnàjò Eliṣa

Ìrìn-àjò

Àwọn ìrìnàjò Eliṣa

Láti Jọdani dé Bẹtẹli, Karmeli, Ṣunemu àti Samaria · Iye ibùdó: 9 · ≈ 330 km ní ìlà tààrà

Odò Jọ́dánìJabbokMe JakoniKidironiSAMARIAÒkè TaboriÒkè NeboJordaniJerikoBeteliÒkè KarmeliSamariaṢunemuGilgaliDotani20 km12345678

© OpenStreetMap contributors

Àwọn ibùdó

  1. Jordani2Ọb 2:13Ó sì mú agbádá tí ó ti jábọ́ láti ọ̀dọ̀ Elijah ó sì padà lọ, ó sì dúró lórí bèbè Jordani.
  2. Jeriko2Ọb 2:18Nígbà tí wọ́n padà dé ọ̀dọ̀ Eliṣa, tí ó dúró ní Jeriko, ó wí fún wọn pé, “Ṣé èmi kò sọ fún un yín kí ẹ má lọ?”
  3. Beteli2Ọb 2:23Láti ibẹ̀ Eliṣa lọ sókè ní Beteli gẹ́gẹ́ bí ó ti ń rìn lọ lójú ọ̀nà, àwọn ọ̀dọ́ kan jáde wá láti ìlú náà wọ́n sì fi ṣe ẹlẹ́yà. “Máa lọ sókè ìwọ apárí!” Wọ́n wí pé. “Máa lọ sókè ìwọ apárí!”
  4. Òkè Karmeli2Ọb 2:25Ó sì lọ sí orí òkè Karmeli láti ibẹ̀ ó sì padà sí Samaria.
  5. Samaria2Ọb 2:25Ó sì lọ sí orí òkè Karmeli láti ibẹ̀ ó sì padà sí Samaria.
  6. Ṣunemu2Ọb 4:8Ní ọjọ́ kan Eliṣa lọ sí Ṣunemu. Obìnrin ọlọ́rọ̀ kan sì wà níbẹ̀, ẹni tí ó rọ̀ ọ́ kí ó dúró jẹun. Bẹ́ẹ̀ ni nígbàkígbà tí ó bá ń kọjá lọ, ó máa ń dúró níbẹ̀ láti jẹun.
  7. Gilgali2Ọb 4:38Eliṣa padà sí Gilgali ìyàn sì wà ní ilẹ̀ náà. Nígbà tí àwọn ọmọ wòlíì ṣe ìpàdé pẹ̀lú rẹ̀, ó sì wí fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé, “Gbé ìkòkò ńlá ka iná kí o sì se ọbẹ̀ aláta díẹ̀ fún àwọn ọkùnrin yìí.”
  8. Dotani2Ọb 6:13Ọba pa á láṣẹ, “Lọ, kí ẹ lọ wo ibi tí ó wà, kí èmi kí ó lè rán ènìyàn láti lọ mú un wá.” Ìròyìn padà wá wí pé, “Ó wà ní Dotani.”
  9. Samaria2Ọb 6:19Eliṣa sọ fún wọn pé, “Èyí kì í ṣe ọ̀nà bẹ́ẹ̀ ni èyí kì í ṣe ìlú náà. Tẹ̀lé mi, èmi yóò mú u yín lọ sí ọ̀dọ̀ ọkùnrin tí ẹ̀yin ń wá.” Ó sì sìn wọ́n lọ sí Samaria.

Àwọn ìlà so àwọn ibùdó pọ̀ ní ìtẹ̀léra ọ̀rọ̀ inú ìwé. Níbi tí ìlà bá tẹ̀lé ilẹ̀, ọ̀nà tí ó ṣeé ṣe ni, gẹ́gẹ́ bí ọ̀mọ̀wé kan ṣe tún un gbé kalẹ̀; níbòmíràn ó tààrà — a kò mọ ọ̀nà náà. Àwọn ijìnnà jẹ́ ìlà tààrà láàrin àwọn ibùdó. Ìlà kékèké: nínú ọkọ̀ ojú omi. Àwọ̀ fẹ́ẹ́rẹ́: ibẹ̀ kò dájú.

Àmì kọ̀ọ̀kan ni ibi tí ó ṣeé ṣe jùlọ; àmì tí àwọ̀ rẹ̀ kò ṣe kedere túmọ̀ sí pé a kò mọ̀ dájú. Àwọn ibi tí a kò mọ ibi tí wọ́n wà kò sí lórí máàpù.

Orísun: OpenBible.info, CC BY 4.0 · UBS Bible Routes, Dr Leen Ritmeyer © United Bible Societies 2023, CC BY-SA 4.0 · Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní · © 2009, 2017 Biblica, Inc., CC BY-SA 4.0; changed: footnotes, headings and the letters over Psalm 119 left out, verses in the app's numbering. The original work by Biblica, Inc. is available for free at www.biblica.com and open.bible. · Orísun àti ẹ̀tọ́