Ojú-ìwé àkọ́kọ́ › Ìwé kíkà Bíbélì ojoojúmọ́ › Oṣù Ògún 2027 › 10 Oṣù Ògún
Kàlẹ́ńdà Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì · 28 Oṣù Agẹmọ (kàlẹ́ńdà àtijọ́)
Ìwé kíkà Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ọjọ́ náà — 10 Oṣù Ògún 2027
Ọjọ́ Ìṣẹ́gun · Ọ̀sẹ̀ kẹjọ lẹ́yìn Pentikosti · Ohùn 6
Àjọ̀dún àti ẹni mímọ́
Apostles of the 70 and Deacons: Prochorus, Nicanor, Timon and Parmenas (1st C)
Àwẹ̀
Kò sí àwẹ̀
Èyí tẹ̀lé òfin ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ (monastic). Nínú ìjọ àdúgbò, a máa ń pinnu ìwọ̀n àwẹ̀ pẹ̀lú àlùfáà ìjẹ́wọ́ ẹni, gẹ́gẹ́ bí ìlera, ọjọ́ orí àti ipò ẹni.
Ìwé kíkà ọjọ́ náà
Episteli
5Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀lọpọ̀ wọn ni inú Ọlọ́run kò dún sí; nítorí a pa wọ́n run nínú aginjù. 6Àwọn nǹkan wọ̀nyí sì jásí àpẹẹrẹ fún àwa, kí a má ṣe ní ìfẹ́ sí àwọn ohun búburú gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn yìí ṣe ní ìfẹ́ si. 7Kí ẹ̀yin kí ó má ṣe jẹ́ abọ̀rìṣà gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti ṣe; gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ pé, “Àwọn ènìyàn náà jókòó láti jẹ àti láti mu, wọ́n sì dìde dúró láti ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́.” 8Bẹ́ẹ̀ ni kí àwa kí ó má ṣe ṣe àgbèrè gẹ́gẹ́ bí àwọn mìíràn nínú wọn ti ṣe, tí ẹgbẹ̀rún méjìlélógún ó lé lẹgbẹ̀rún (23,000) ènìyàn sì kú ní ọjọ́ kan. 9Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin má ṣe dán Olúwa wò, gẹ́gẹ́ bí àwọn mìíràn nínú wọn ti dán an wò, tí a sì fi ejò run wọ́n. 10Bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin kí ó má ṣe kùn, gẹ́gẹ́ bí àwọn mìíràn nínú wọ́n ṣe kùn, tí a sì ti ọwọ́ olùparun run wọ́n. 11Gbogbo àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣẹlẹ̀ sí wọn bí àpẹẹrẹ fún wa, a sì kọ̀wé wọn fún ìkìlọ̀ fún wa, àwa ẹni tí ìgbẹ̀yìn ayé dé bá. 12Nítorí náà, ẹni tí ó bá rò pé òun dúró, kí ó kíyèsára kí ó ma ba à ṣubú.
Ìyìnrere
6Jesu sì kìlọ̀ fún wọn pé, “Ẹ kíyèsára, ẹ sì ṣọ́ra, ní ti ìwúkàrà àwọn Farisi àti àwọn Sadusi.” 7Wọ́n ń sọ eléyìí ni àárín ara wọn wí pé, “Nítorí tí àwa kò mú àkàrà lọ́wọ́ ni.” 8Nígbà tí ó gbọ́ ohun ti wọ́n ń sọ, Jesu béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Ẹ̀yin onígbàgbọ́ kékeré, èéṣe tí ẹ̀yin ń dààmú ara yín pé ẹ̀yin kò mú oúnjẹ lọ́wọ́? 9Tàbí ọ̀rọ̀ kò yé yín di ìsinsin yìí? Ẹ̀yin kò rántí pé mo bọ́ ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) ènìyàn pẹ̀lú ìṣù àkàrà márùn-ún àti iye agbọ̀n tí ẹ kójọ bí àjẹkù? 10Ẹ kò sì tún rántí ìṣù méje tí mo fi bọ́ ẹgbàajì (4,000) ènìyàn àti iye agbọ̀n tí ẹ̀yín kójọ? 11Èéha ṣe tí kò fi yé yín pé èmi kò sọ̀rọ̀ nípa ti àkàrà? Lẹ́ẹ̀kan sí i, mo wí fún yín, ẹ ṣọ́ra fún ìwúkàrà àwọn Farisi àti ti Sadusi.” 12Nígbà náà ni ó ṣẹ̀ṣẹ̀ wáyé wọn pé, kì í ṣe nípa ti ìwúkàrà ní ó sọ wí pé kí wọ́n kíyèsára, bí kò ṣe tí ẹ̀kọ́ àwọn Farisi àti Sadusi.
Àwọn déètì tẹ̀lé kàlẹ́ńdà Júlíọ̀sì ti Ìjọ Rọ́ṣíà (bí àwọn Ìjọ Sẹ́bíà àti Jọ́jíà àti Òkè Athos ti ń ṣe): 28 Oṣù Agẹmọ nínú kàlẹ́ńdà ìjọ ni 10 Oṣù Ògún nínú kàlẹ́ńdà ìlú. Àwọn Ìjọ tí ń lo kàlẹ́ńdà tuntun (Gíríìsì, Romania, Bulgaria, Ukraine…) ń ṣe àwọn àjọ̀dún tí kò yí padà àti àwọn ẹni mímọ́ ní déètì ìlú gan-an, ọjọ́ 13 ṣáájú, àwọn kan lára ìwé kíkà wọn sì yàtọ̀; Àjíǹde àti àwọn ọjọ́ tí ó gbára lé e jẹ́ ọ̀kan náà.
Orísun: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní · © 2009, 2017 Biblica, Inc., CC BY-SA 4.0; changed: footnotes, headings and the letters over Psalm 119 left out, verses in the app's numbering. The original work by Biblica, Inc. is available for free at www.biblica.com and open.bible. · Orísun àti ẹ̀tọ́