Bible Explorer Gba àpù

Ṣàwárí › Ìrìn-àjò › Gideoni lépa àwọn ará Midiani

Ìrìn-àjò

Gideoni lépa àwọn ará Midiani

Láti orísun Harodu dé Sukoti àti Penueli · Iye ibùdó: 6 · ≈ 260 km ní ìlà tààrà

ArnoniAMMONIHarodiBeti-SittaAbeli-MeholaSukkotiPenieliKarkori50 km123456

© OpenStreetMap contributors

Àwọn ibùdó

  1. HarodiOn 7:1Ní òwúrọ̀ kùtùkùtù Jerubbaali (èyí ni Gideoni) pẹ̀lú gbogbo àwọn ọmọ-ogun tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ kó ogun jọ lẹ́bàá a orísun Harodi. Àwọn ogun Midiani sì wà ní apá àríwá tí wọ́n ní àfonífojì tí ó wà ní ẹ̀bá òkè More.
  2. Beti-SittaOn 7:22Nígbà tí àwọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ọkùnrin wọ̀n-ọn-nì fun fèrè wọn, Olúwa sì yí ojú idà ọkùnrin kọ̀ọ̀kan padà sí ẹnìkejì rẹ̀ àti sí gbogbo ogun wọn. Àwọn ọmọ-ogun sì sá títí dé Beti-Sitta ní ọ̀nà Serera títí lọ dé ìpínlẹ̀ Abeli-Mehola ní ẹ̀bá Tabbati.
  3. Abeli-MeholaOn 7:22Nígbà tí àwọn ọ̀ọ́dúnrún (300) ọkùnrin wọ̀n-ọn-nì fun fèrè wọn, Olúwa sì yí ojú idà ọkùnrin kọ̀ọ̀kan padà sí ẹnìkejì rẹ̀ àti sí gbogbo ogun wọn. Àwọn ọmọ-ogun sì sá títí dé Beti-Sitta ní ọ̀nà Serera títí lọ dé ìpínlẹ̀ Abeli-Mehola ní ẹ̀bá Tabbati.
  4. SukkotiOn 8:5Ó wí fún àwọn ọkùnrin Sukkoti pé, “Ẹ fún àwọn ọmọ-ogun mi ní oúnjẹ díẹ̀, nítorí ó ti rẹ̀ wọ́n, èmi sì ń lépa Seba àti Salmunna àwọn ọba Midiani.”
  5. PenieliOn 8:8Láti ibẹ̀, ó lọ sí Penieli ó sì bẹ̀ wọ́n bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ṣùgbọ́n àwọn náà dá a lóhùn bí àwọn ará Sukkoti ti dá a lóhùn.
  6. KarkoriOn 8:10Ní àsìkò náà Seba àti Salmunna wà ní Karkori pẹ̀lú ọmọ-ogun wọn tí ó tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún (15,000) ọkùnrin, àwọn wọ̀nyí ni ó ṣẹ́kù nínú gbogbo ogun àwọn ènìyàn apá ìlà-oòrùn, nítorí ọ̀kẹ́ mẹ́fà (120,000) ọkùnrin tí ó fi idà jà ti kú ní ojú ogun.

Àwọn ìlà so àwọn ibùdó pọ̀ ní ìtẹ̀léra ọ̀rọ̀ inú ìwé. Níbi tí ìlà bá tẹ̀lé ilẹ̀, ọ̀nà tí ó ṣeé ṣe ni, gẹ́gẹ́ bí ọ̀mọ̀wé kan ṣe tún un gbé kalẹ̀; níbòmíràn ó tààrà — a kò mọ ọ̀nà náà. Àwọn ijìnnà jẹ́ ìlà tààrà láàrin àwọn ibùdó. Ìlà kékèké: nínú ọkọ̀ ojú omi. Àwọ̀ fẹ́ẹ́rẹ́: ibẹ̀ kò dájú.

Àmì kọ̀ọ̀kan ni ibi tí ó ṣeé ṣe jùlọ; àmì tí àwọ̀ rẹ̀ kò ṣe kedere túmọ̀ sí pé a kò mọ̀ dájú. Àwọn ibi tí a kò mọ ibi tí wọ́n wà kò sí lórí máàpù.

Orísun: OpenBible.info, CC BY 4.0 · UBS Bible Routes, Dr Leen Ritmeyer © United Bible Societies 2023, CC BY-SA 4.0 · Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní · © 2009, 2017 Biblica, Inc., CC BY-SA 4.0; changed: footnotes, headings and the letters over Psalm 119 left out, verses in the app's numbering. The original work by Biblica, Inc. is available for free at www.biblica.com and open.bible. · Orísun àti ẹ̀tọ́