Ojú-ìwé àkọ́kọ́ › Ìwé kíkà Bíbélì ojoojúmọ́ › Oṣù Bélú 2027 › 19 Oṣù Bélú
Kàlẹ́ńdà Kátólíìkì
Ìwé kíkà Máàsì (Kátólíìkì) — 19 Oṣù Bélú 2027
Ọjọ́ Ẹtì · Ọ̀sẹ̀ 33 ti Àkókò Lásán
Àjọ̀dún àti ẹni mímọ́
Ọjọ́ Ẹtì ọ̀sẹ̀ 33 ti Àkókò Lásán
Ọjọ́ ọ̀sẹ̀ · Àwọ̀ ìsìn: ewé
Àwẹ̀ àti ìrònúpìwàdà
Ọjọ́ ìrònúpìwàdà
Gbogbo Ọjọ́ Ẹtì jẹ́ ọjọ́ ìrònúpìwàdà; àjọ àwọn bíṣọ́ọ̀bù kọ̀ọ̀kan ló ń pinnu bí a ṣe ń pa á mọ́: ìyàgò fún ẹran tàbí iṣẹ́ ìrònúpìwàdà mìíràn. Àwẹ̀ dè àwọn ọmọ ọdún 18 sí 59, ìyàgò fún ẹran dè láti ọmọ ọdún 14.
Ìwé kíkà ọjọ́ náà
Ìwé kíkà kìn-ín-ní
Kò sí nínú ìtumọ̀ yìí
Saamu ìdáhùn
10Dafidi yin Olúwa níwájú gbogbo àwọn tí ó péjọ, wí pé, “Ìyìn ni fún Ọ, Olúwa, Ọlọ́run baba a wa Israẹli, láé àti láéláé. 11Tìrẹ Olúwa ni títóbi àti agbára pẹ̀lú ìyìn àti ọláńlá àti dídán, nítorí tí gbogbo nǹkan ní ọ̀run àti ayé jẹ́ tìrẹ. Tìrẹ Olúwa ni ìjọba; a gbé ọ ga gẹ́gẹ́ bí orí lórí ohun gbogbo. 12Ọlá àti ọ̀wọ̀ wá láti ọ̀dọ̀ Rẹ; ìwọ ni alákòóso gbogbo nǹkan. Ní ọwọ́ rẹ ni ipá àti agbára wà láti gbéga àti láti fi agbára fún ohun gbogbo.
Ìyìnrere
45Ó sì wọ inú tẹmpili lọ, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí lé àwọn tí ń tà nínú rẹ̀ sóde; 46Ó sì wí fún wọn pé, “A ti kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Ilé mi yóò jẹ́ ilé àdúrà?’ Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti sọ ọ́ di ihò àwọn ọlọ́ṣà.” 47Ó sì ń kọ́ni lójoojúmọ́ ní tẹmpili, ṣùgbọ́n àwọn olórí àlùfáà, àti àwọn akọ̀wé, àti àwọn olórí àwọn ènìyàn ń wá ọ̀nà láti pa á. 48Wọn kò sì rí nǹkan kan tí wọn ìbá ṣe; nítorí gbogbo ènìyàn ṣù mọ́ ọn láti gbọ́rọ̀ rẹ̀.
Kàlẹ́ńdà Róòmù gbogbogbò; àpéjọ àwọn bíṣọ́ọ̀bù lè gbé àwọn ayẹyẹ kan (Ìfarahàn Olúwa, Ìgòkè-re-ọ̀run, Ara àti Ẹ̀jẹ̀ Krístì) lọ sí ọjọ́ Àìkú tàbí fi tiwọn kún un. Ìwé ìkàwé: àyíká ọjọ́ Àìkú B, ọdún ọjọ́ ọ̀sẹ̀ I.
Orísun: Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní · © 2009, 2017 Biblica, Inc., CC BY-SA 4.0; changed: footnotes, headings and the letters over Psalm 119 left out, verses in the app's numbering. The original work by Biblica, Inc. is available for free at www.biblica.com and open.bible. · Orísun àti ẹ̀tọ́