Bible Explorer

Ojú-ìwé àkọ́kọ́ › Ohun tí Bíbélì sọ › Ìgbéyàwó

Àjọṣepọ̀

Ohun tí Bíbélì sọ nípa Ìgbéyàwó

Àwọn ẹsẹ tí àwọn òǹkàwé máa ń yíjú sí jùlọ fún àkòrí yìí (10), tí a fà yọ ní kíkún láti inú Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní.

Hb 13:4Kí ìgbéyàwó lọ́lá láàrín gbogbo ènìyàn, kí àkéte si jẹ́ aláìléèérí, nítorí àwọn àgbèrè àti àwọn panṣágà ni Ọlọ́run yóò dá lẹ́jọ́.
Gẹ 2:24Nítorí ìdí èyí, ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, yóò sì dàpọ̀ mọ́ aya rẹ̀, wọn yóò sì di ara kan.
Òw 18:22Ẹni tí ó rí aya fẹ́, rí ohun rere, o sì gba ojúrere lọ́dọ̀ Olúwa.
1Pt 3:7Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa fi òye ba àwọn aya yín gbé, ẹ máa fi ọlá fún aya, bi ohun èlò ti kò lágbára, àti pẹ̀lú bí àjùmọ̀jogún oore-ọ̀fẹ́ ìyè; kí àdúrà yín má bà á ní ìdènà.
Gẹ 2:18Olúwa Ọlọ́run wí pé, “Kò dára kí ọkùnrin wà ní òun nìkan. Èmi yóò ṣe olùrànlọ́wọ́ tí ó rí bí i rẹ̀ fún un.”
Ef 5:25Ẹ̀yin ọkọ, ẹ fẹ́ràn àwọn aya yín, gẹ́gẹ́ bí Kristi tí fẹ́ràn ìjọ, tí ó sì fi ara rẹ̀ fún un.
Òw 19:14A máa ń jogún ilé àti ọrọ̀ lọ́dọ̀ òbí, ṣùgbọ́n aya olóye láti ọ̀dọ̀ Olúwa ni.
Kl 3:19Ẹ̀yin ọkọ, ẹ máa fẹ́ràn àwọn aya yín, ẹ má sì ṣe korò sí wọn.
Mt 19:4–6Ó dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ẹyin kò ti kà á pé ‘ẹni tí ó dá wọn ní ìgbà àtètèkọ́ṣe, Ọlọ́run dá wọn ni ti akọ ti abo.’ Ó sì wí fún un pé, ‘Nítorí ìdí èyí ọkùnrin yóò fi baba àti ìyá rẹ̀ sílẹ̀, òun yóò sì dàpọ̀ mọ́ aya rẹ̀, àwọn méjèèjì yóò sì di ara kan.’ Wọn kì í túnṣe méjì mọ́, ṣùgbọ́n ara kan. Nítorí náà, ohun tí Ọlọ́run bá ti so ṣọ̀kan, kí ẹnikẹ́ni má ṣe yà wọ́n.”
Òw 31:10Ta ni ó le rí aya oníwà rere? Ó níye lórí ju iyùn lọ.

Àwọn ẹsẹ tí àwọn òǹkàwé máa ń wá jù fún kókó yìí nìyí — kì í ṣe ẹ̀kọ́ nípa rẹ̀. Ka ọ̀kọ̀ọ̀kan nínú orí rẹ̀.

Orísun

Àwọn ẹsẹ àkòrí kọ̀ọ̀kan àti ètò wọn: dátà àkòrí OpenBible.info, gẹ́gẹ́ bí ìbò àwọn òǹkàwé: OpenBible.info · CC BY 4.0

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní · © 2009, 2017 Biblica, Inc., CC BY-SA 4.0; changed: footnotes, headings and the letters over Psalm 119 left out, verses in the app's numbering. The original work by Biblica, Inc. is available for free at www.biblica.com and open.bible.