YCB · Orí 14 / 42
Jobu 14
1“Ènìyàn tí a bí nínú obìnrin, ọlọ́jọ́ díẹ̀ ni, ó sì kún fún ìpọ́njú.
2Ó jáde wá bí ìtànná ewéko, a sì ké e lulẹ̀; ó sì ń fò lọ bí òjìji, kò sì dúró pẹ́.
3Ìwọ sì ń síjú rẹ wò irú èyí ni? Ìwọ sì mú mi wá sínú ìdájọ́ pẹ̀lú rẹ?
4Ta ni ó lè mú ohun mímọ́ láti inú àìmọ́ jáde wá? Kò sí ẹnìkan!
5Ǹjẹ́ a ti pinnu ọjọ́ rẹ̀, iye oṣù rẹ̀ ń bẹ ní ọwọ́ rẹ, ìwọ ti pààlà rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ní òun kò le kọjá rẹ̀.
6Yípadà kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, kí ó lè sinmi, títí yóò fi pé ọjọ́ rẹ̀ bí alágbàṣe.
7“Nítorí pé ìrètí wà fún igi, bí a bá ké e lulẹ̀, pé yóò sì tún sọ, àti pé ẹ̀ka rẹ̀ tuntun kì yóò gbẹ.
8Bí gbòǹgbò rẹ̀ tilẹ̀ di ogbó nínú ilẹ̀, tí kùkùté rẹ̀ si kú ni ilẹ̀,
9síbẹ̀ nígbà tí ó bá gbóòórùn omi, yóò sọ, yóò sì yọ ẹ̀ka jáde bí irúgbìn.
10Ṣùgbọ́n ènìyàn kú, a sì dàánù, àní ènìyàn jọ̀wọ́ ẹ̀mí rẹ̀ lọ́wọ́: Òun kò sì sí mọ́.
11“Bí omi ti í tán nínú ipa odò, àti bí odò ṣì tí í fà tí sì gbẹ,
12bẹ́ẹ̀ ni ènìyàn dùbúlẹ̀ tí kò sì dìde mọ́; títí ọ̀run kì yóò fi sí mọ́, wọ́n kì yóò jí, a kì yóò jí wọn kúrò lójú oorun wọn.
13“Háà! ìwọ ìbá fi mí pamọ́ ní ipò òkú, kí ìwọ kí ó fi mí pamọ́ ní ìkọ̀kọ̀, títí ìbínú rẹ yóò fi rékọjá, ìwọ ìbá lànà ìgbà kan sílẹ̀ fún mi, kí ó si rántí mi!
14Bí ènìyàn bá kú yóò sì tún yè bí? Gbogbo ọjọ́ ìgbà tí a là sílẹ̀ fún mi ni èmi dúró dè, títí àmúdọ̀tún mi yóò fi dé.
15Ìwọ ìbá pè, èmi ìbá sì dá ọ lóhùn; ìwọ ó sì ní ìfẹ́ sì iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.
16Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ìwọ ń kaye ìṣísẹ̀ mi; ìwọ kò fa ọwọ́ rẹ kúrò nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mi?
17A fi èdìdì di ìrékọjá mi sínú àpò, ìwọ sì rán àìṣedéédéé mi pọ̀.
18“Àti nítòótọ́ òkè ńlá tí ó ṣubú, ó dasán, a sì ṣí àpáta kúrò ní ipò rẹ̀.
19Omi a máa yinrin òkúta, ìwọ a sì mú omi sàn bo ohun tí ó hù jáde lórí ilẹ̀, ìwọ sì sọ ìrètí ènìyàn dí òfo.
20Ìwọ ṣẹ́gun rẹ̀ láéláé, òun sì kọjá lọ! Ìwọ pa awọ ojú rẹ̀ dà, o sì rán an lọ kúrò.
21Àwọn ọmọ rẹ̀ bọ́ sí ipò ọlá, òun kò sì mọ̀; wọ́n sì rẹ̀ sílẹ̀, òun kò sì kíyèsi i lára wọn.
22Ṣùgbọ́n ẹran-ara rẹ̀ ni yóò rí ìrora ọkàn rẹ̀ ni yóò sì máa ní ìbìnújẹ́ nínú rẹ̀.”
Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB, 2017) · © 2009, 2017 Biblica, Inc., CC BY-SA 4.0; changed: footnotes, headings and the letters over Psalm 119 left out, verses in the app's numbering. The original work by Biblica, Inc. is available for free at www.biblica.com and open.bible. (ọ̀rọ̀ kò yí padà; a fi àkíyèsí ìsàlẹ̀ àti àkọlé sílẹ̀) · eBible.org